Gospel Global Sola Allyson – Isin

Sola Allyson – Isin

Download Isin MP3 byย Sola Allyson

Here an amazing song from the Nigerian soul, folk and gospel singer, and song-writer, who came into limelight with the hit album Eji Owuro.ย Sola Allyson-Obaniyiย who is popularlyย knownย as Shola Allyson comes through with this song titled โ€œIsinโ€œ.

Get Audio Mp3, Stream, Share, and stay blessed alwaysโ€ฆ

DOWNLOAD MP3 HERE

Download More SOLA ALLYSON Songs Here

Lyrics: Isin byย Sola Allyson

A f’ope f’Olorun
L’okan ati l’ohun wa
Eni s’ohun ‘yanu
N’nu Eni t’araye n yo
Gbat’a wa l’om’owo
On na l’o ntoju wa
O si f’ebun ife
Se ‘toju wa sibe
Oba Onibuore
Ma fi wa sile laelae
Ayo ti ko l’opin
On ‘bukun y’o je ti wa
Pa wa mo ninu oore
To wa, gb’a ba damu
Yo wa ninu ibi
L’aye ati l’orun
K’a f’iyin on ope
F’Olorun, Baba, Omo
Ati Emi mimo
Ti o ga julo lorun
Olorun kan laelae
T’aye at’orun n bo
Bee lo wa di isiyi
Beeni yo wa laelae
Eyo ninu Oluwa, e yo
Eyin t’okan re se dede
Eyin t’o ti yan Oluwa
Le ‘banuje at’aro lo
E yo! E yo!
E yo ninu Oluwa, e yo!
E yo! E yo!
E yo ninu Oluwa, e yo!
E yo tor’ On l’Oluwa
L’aye ati l’orun pelu
Oro Re bor’ ohun gbogbo
O l’agbara lati gbala
E yo! E yo!
E yo ninu Oluwa, e yo!
E yo! E yo
E yo ninu Oluwa, e yo!
‘Gbat’ a ba n ja ija rere
Ti ota fere bori wa
Ogun Olorun t’a ko ri
Po ju awon ota wa lo
E yo! E yo!
E yo ninu Oluwa, e yo!
E yo! E yo
E yo ninu Oluwa, e yo!
Okan mi n yo ninu Oluwa
‘Tori O je iye fun mi
Ohun Re dun pupo lati gbo
Adun ni lati r’oju Re
Emi n yo ninu Re
Emi n yo ninu Re
Gba gbogbo lo n fi ayo kun okan mi
‘Tori emi n yo ninu Re
O ti n wa mi pe ki n to mo O
‘Gbati mo rin jina s’agbo
O gbe mi wa sile l’apa Re
Nibi ti papa tutu wa
Emi n yo ninu Re
Emi n yo ninu Re
Gba gbogbo lo n fi ayo kun okan mi
‘Tori emi nyo ninu Re
Oore at’anu Re yi mi ka
Or’ofe Re n san bi odo
Emi Re n to, o si n se ‘tunu
O mba mi lo si ‘bikibi
Emi n yo ninu Re
Emi n yo ninu Re
Gba gbogbo lo n fi ayo kun okan mi
‘Tori emi nyo ninu Re
Iwo to fe wa la o ma sin titi
Oluwa Oloore wa
Iwo to nso wa ninu ‘danwo aye
Mimo logo Ola Re
Baba, Iwo l’a o ma sin
Baba, Iwo l’a o ma bo
Iwo to fe wa l’a o ma sin titi
Mimo l’ogo ola Re
Iwo to f’agan l’omo to n pe ranse
Ninu ola Re to ga
Eni t’o ti s’alaileso si n dupe
Fun ‘se ogo ola Re
Baba, Iwo l’a o ma sin
Baba, Iwo l’a o ma bo
Iwo to fe wa l’a o ma sin titi
Mimo l’ogo ola Re
Eni t’ebi n pa le ri ayo ninu
Agbara nla Re to ga o
Awon to ti n woju Re fun aanu
Won tun n yo ninu ise Re
Baba, Iwo l’a o ma sin
Baba, Iwo l’a o ma bo
Iwo to fe wa l’a o ma sin titi
Mimo l’ogo ola Re
Baba E se aanu Yin duro
Baba E se o
Baba E se o, aanu Yin duro
Baba E se aanu Yin duro
Baba E se
Baba E se o
Baba E se, aanu Yin duro
Eyin ni o, Olorun o
Eledumare, Oba ogo
Eyin ni o, Olorun
Awimayehun, Alagbara
Eyin ni o, Olorun o
Eledumare, Oga ogo
Eyin ni o, Olorun o
Awimayehun, Alagbara
K’a to da aye, n’Iwo ti wa
K’ole mi to so ninu iya mi, l’O ti n joba
Olorun Baba o, Olorun omo
Olorun Emi mimo
Iwo n’ibere ohun gbogbo
Iwo ni opin ohun gbogbo
Awimayehun, Alagbara
Eyin ni o, Olorun o
Eledumare, Oga ogo
Eyin ni o, Olorun o
Awimayehun, Alagbara
Oluwa orun on aye
‘Wo n’iyin at’ope ye fun
Bawo la ba ti fe O to!
Onibu ore
Orun ti n ran, at’ afefe
Gbogbo eweko n so ‘fe Re
‘Wo l’O n mu irugbin dara
Onibu ore
Onibu ore
Bawo la ba ti fe O to!
Onibu ore
Fun ara lile wa gbogbo
Fun gbogbo ibukun aye
Awa yin O, a si dupe
Onibu ore
Fun idariji ese wa
Ati fun ireti orun
Ki l’ohun t’a ba fifun O
Onibu ore
Onibu ore
Bawo la ba ti fe O to!
Onibu ore
O se mi laanu, ma a polongo Re
Oba t’o se mi laanu, eh eh, ah ah
Ma a polongo Re
O se mi laanu, ma a polongo Re
Oba t’o se mi laanu, eh eh, ah ah
Ma a polongo Re
Oju mi ti ri, eti mi ti gbo
Enu mi ma soro n’pa ise Oluwa
Oju mi ti ri o, eti mi ti gbo
Enu mi ma soro n’pa ise Oluwa
Oju mi ti ri, eti mi ti gbo
Enu mi ma soro n’pa ise Oluwa
Oju mi ti ri, eti mi ti gbo
Enu mi ma soro n’pa ise Oluwa
Olori ijo t’orun
L’ayo l’a wole fun O
K’O to de, ijo t’aye
Y’o ma korin bi t’orun
A gbe okan wa s’oke
Ni ‘reti t’o ni ‘bukun
Awa kigbe, awa f’iyin
F’Olorun igbala wa
Bi a wa ninu ‘ponju
T’a n koja ninu ina
Orin ife l’awa yo ko
Ti yo mu wa sun mo O
Awa n sape, a si yo
Ninu ojurere Re
Ife t’o so wa di Tire
Y’o pa wa mo titi lae
Iwo mu awon eeyan Re
Koja isan idanwo
A k’ yo beru wahala
Tori O wa nitosi
Aye, ese, at’Esu
Koju ‘ja si wa lasan
L’agbara Re, a o segun
A o si ko orin Mose
Aribiti, Arabata
Eyin l’atobiju
Aribiti, Arabata
Eyin l’atobiju
Oluwa
Oluwa, Eyin l’atobiju
Aribiti, Arabata
Eyin l’atobiju
Aribiti, Arabata
Eyin l’atobiju
Oluwa
Lat’ojo ti mo ti n rin
Eh oh, eh eh eh eh oh
Emi o ri ‘ru Olorun eyi ri
Eh oh, eh oh
Lat’ojo ti mo ti n rin
Eh oh, eh oh
Emi o ri ‘ru Olorun eyi ri
Eh oh, eh oh
Ojo nla l’ojo ti mo yan
Olugbala l’Olorun mi
O ye ki okan mi ma yo
K’o si ro ihin na kale
Ojo nla l’ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
O ko mi ki n ma gbadura
Ki n ma sora, ki n si ma yo
Ojo nla l’ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
Ise igbala pari na
Emi di t’Oluwa mi loni ati lojo gbogbo
Ohun l’o pe mi, ti mo si je o
Mo f’ayo j’ipe mimo na
Ojo nla l’ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
O ko mi ki n ma gbadura
Ki n ma sora, ki n si ma yo
Ojo nla l’ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
Eyin orun gbo eje mi,
Eje mi ni ojojumo
Emi y’o ma so dotun titi
Iku yo fi mu mi rele
Ojo nla l’ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
O ko mi ki n ma gbadura
Ki n ma sora, ki n si ma yo
Ojo nla l’ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
Gbese ope mi po, emi o le san tan
Amo o sibesibe, ma a se ‘won ti mo le se
Baba Alaanu mi, E ma se o Baba
Gbese ope mi po, emi o le san tan
Amo o sibesibe, ma a se ‘won ti mo le se
Baba Alaanu mi, E ma se o Baba
Mo n tesiwaju l’ona na
Mo n goke sii lojojumo
Mo n gbadura bi mo ti n lo
Oluwa jo gbe mi soke
Oluwa, jo gbe mi soke
Fa mi lo si ibi giga
Apata t’o ga ju mi lo
Oluwa jo gbe mi soke
Ife okan mi ko duro
Laarin ‘yemeji at’eru
Awon miran le ma gbe be
Ibi giga l’okan mi n fe
Oluwa, jo gbe mi soke
Fa mi lo si ibi giga
Apata t’o ga ju mi lo
Oluwa jo gbe mi soke
Mo fe de ‘bi giga julo
Ninu ogo didan julo
Mo n gbadura ki n le de be
Oluwa mu mi de ‘le na
Oluwa, jo gbe mi soke
Fa mi lo si ibi giga
Apata t’o ga ju mi lo
Oluwa jo gbe mi soke
Igbagbo mi duro l’ori
Eje at’ ododo Jesu
N ko je gbekele ohun kan
Leyin oruko nla Jesu
Mo duro le Kristi Apata
Ile miran, iyanrin ni
Mo duro le Kristi Apata
Ile miran, iyanrin ni
B’ire-ije mi tile gun
Ore-ofe Re ko yi pada
B’o ti wu ki iji na le to
Idakoro mi ko niye
Mo duro le Kristi Apata
Ile miran, iyanrin ni
Mo duro le Kristi Apata
Ile miran, iyanrin ni
Ore-ofe, ohun
Adun ni l’eti wa
Gbohun-gbohun re y’o gba orun kan
Aye y’o gbo pelu
Ore-Ofe sa
N’igbekele mi
Jesu ku fun araye
O ku fun mi pelu
Ore-Ofe to mi
S’ona alaafia
O n toju mi l’ojojumo
Ni irin ajo mi
Ore-Ofe sa
N’igbekele mi
Jesu ku fun araye
O ku fun mi pelu
Je k’ ore-ofe yi
F’agbara fokan mi
Ki n le fi gbogbo ipa mi
At’ ojo mi fun O
Ore-Ofe sa
N’igbekele mi
Jesu ku fun araye
O ku fun mi pelu
Ninu irin ajo mi, beeni mo n korin
Mo n toka si Kalfari, nibi eje na
Idanwo lode ninu, l’ota gbe dide
Jesu l’O nto mi lo, isegun daju
A! mo fe ri Jesu, ki n ma w’ oju Re
Ki n ma korin titi, nipa oore Re
Ni ilu ogo ni, ki n gbohun soke
Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi
Ninu ise isin mi, b’okunkun ba su
Un o tubo sunmo Jesu, y’O tan imole
Esu le gb’ ogun ti mi ki nle sa pada
Jesu l’o nto mi lo, ko s’ewu fun mi
A! mo fe ri Jesu, ki n ma w’ oju Re
Ki n ma korin titi, nipa oore Re
Ni ilu ogo ni, ki n gbohun soke
Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi
Bi mo tile bo sinu afonifoji
Imole itoni Re y’o mole si mi
Y’o na owo Re si mi, y’O gbe mi soke
Un o tesiwaju b’O ti n to mi lo
Nigbati iji aye yi ba yi lu mi
Mo ni abo t’o daju labe apa Re
Y’O ma f’owo Re to mi titi de opin
Ore ododo ni, A! mo ti f’E to
A! mo fe ri Jesu, ki n ma w’ oju Re
Ki n ma korin titi, nipa oore Re
Ni ilu ogo ni ki n gbohun soke
Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi
Nipa ife Olugbala
Ki y’o si nkan
Oju rere Re ki pada
Ki y’o si nkan
Owon l’eje t’o wo wa san
Pipe l’edidi or’ofe
Agbara l’owo t’o n gba ni
Ko le si nkan
Bi a wa ninu iponju
Ki y’o si nkan
Igbala kikun ni tiwa
Ki y’o si nkan
Igbekele Olorun dun
Gbigbe ninu Kristi l’ere
Emi si n so wa di mimo
Ko le si nkan
Ojo ola yio dara
Ki y’o si nkan
‘Gbagbo le korin ni ‘ponju
Ki y’o si nkan
A gbekele ‘fe Baba wa
Jesu n fun wa l’ohun gbogbo
Ni yiye tabi ni kiku
Ko le si nkan
Amin.

Comment below with your feedback and thoughts on this post.