Download Igbagbo Mi Duro Lori Mp3 by Tabernacle Mass Choir
Lyrics: Igbagbo Mi Duro Lori by Tabernacle Mass Choir
Igbagbo mi duro, l’ori
Eje at’ ododo Jesu;
Nko je gbekele ohun kan,
Lehin oruko nla Jesu:
Mo duro le Krist’ Apata,
Ile miran, iyanrin ni.
B’ ire-ije mi tile gun,
Or’-ofe Re ko yipada;
B’ o ti wu k’ iji na le to
Idakoro ni ko ni ye
Mo duro le Krist’ Apata,
Ile miran, iyanrin ni.
Majemu ati eje Re,
L’ em’ o romo b’ ikunmi de
Gbati ko s’atilehin mo
O je ireti nla fun mi:
Mo duro le Krist’ Apata
Ile miran, iyanrin ni.
Gbat’ ipe kehin ba si dun,
A! mba le wa ninu Jesu,
Ki nwo ododo Re nikan,
Ki nduro niwaju ite:
Mo duro le Krist’ Apata
Ile miran, iyanrin ni